﻿ÌKÉDE KÁRÍAYÉ FÚN È̟TÓ̟ O̟MO̟NÌYÀN
Ò̟RÒ̟ ÀKÓ̟SO̟
Bí ó ti jé̟ pé s̟ís̟e àkíyèsí iyì tó jé̟ àbímó̟ fún è̟dá àti ìdó̟gba è̟tó̟ t̟̟̟̟í kò s̟eé mú kúrò tí è̟dá kò̟ò̟kan ní, ni òkúta ìpìlè̟ fún òmìnira, ìdájó̟ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé, 
Bí ó ti jé̟ pé àìka àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn sí àti ìké̟gàn àwo̟n è̟tó̟ wò̟nyí ti s̟e okùnfà fún àwo̟n ìwà búburú kan, tó mú è̟rí-o̟kàn è̟dá gbo̟gbé̟, tó sì jé̟ pé ìbè̟rè̟ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̟n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̟ síso̟ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̟n gbó̟, òmìnira ló̟wó̟ è̟rù àti òmìnira ló̟wó̟ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̟ ló̟kàn àwo̟n o̟mo̟-èniyàn,
Bí ó ti jé̟̟ pé ó s̟e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̟n è̟tó o̟mo̟nìyàn lábé̟ òfin, bí a kò bá fé̟ ti àwo̟n ènìyàn láti ko̟jú ìjà sí ìjo̟ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̟nà àbáyo̟ mìíràn fún wo̟n láti bèèrè è̟tó̟ wo̟n,
Bí ó ti jé̟ pé ó s̟e pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbás̟epò̟ ti ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin àwo̟n orílè̟-èdè,
Bí ó ti jé̟ pé gbogbo o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé tún ti te̟nu mó̟ ìpinnu tí wó̟n ti s̟e té̟lè̟ nínú ìwé àdéhùn wo̟n, pé àwo̟n ní ìgbàgbó̟ nínú è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí, ìgbàgbó̟ nínú iyì àti è̟ye̟ è̟dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̟ nínú ìdó̟gba è̟tó̟ láàrin o̟kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̟ pé wó̟n tún ti pinnu láti s̟e ìgbéláruge̟ ìtè̟síwájú àwùjo̟ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé-ayé rere è̟dá ti lè gbòòrò sí i,
Bí ó ti jé̟ pé àwo̟n o̟mo̟ e̟gbé̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ti jé̟jè̟é̟ láti fo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ pè̟lú Àjo̟ náà, kí won lè jo̟ s̟e às̟eyege nípa àmús̟e̟ àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti òmìnira è̟dá tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí àti láti rí i pé à ń bò̟wò̟ fún àwo̟n è̟tó̟ náà káríayé,
Bí ó ti jé̟ pé àfi tí àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmús̟e̟ è̟jé̟ yìí ní kíkún,
Ní báyìí,
Àpapò̟̟ ìgbìmò̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé s̟e ìkéde káríayé ti è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, gé̟gé̟ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̟dá àti orílè̟-èdè jo̟ ń lépa ló̟nà tó jé̟ pé e̟nì kò̟ò̟kan àti è̟ka kò̟ò̟kan láwùjo̟ yóò fi ìkéde yìí só̟kàn, tí wo̟n yóò sì rí i pé àwo̟n lo ètò-ìkó̟ni àti ètò-è̟kó̟ láti s̟e ìgbéláruge̟ ìbò̟wò̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí. Bákan náà, a gbo̟dò̟ rí àwo̟n ìgbésè̟ tí ó lè mú ìlo̟síwájú bá orílè̟-èdè kan s̟os̟o tàbí àwo̟n orílè̟-èdè sí ara wo̟n, kí a sì rí i pé a fi ò̟wò̟ tó jo̟jú wo̟ àwo̟n òfin wò̟nyí, kí àmúlò wo̟n sì jé̟ káríayé láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè tó jé̟ o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan àgbáyé fúnra wo̟n àti láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè mìíràn tó wà lábé̟ às̟e̟ wo̟n.
Abala kìíní.
Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̟tó̟ kò̟ò̟kan sì dó̟gba. Wó̟n ní è̟bùn ti làákàyè àti ti è̟rí-o̟kàn, ó sì ye̟ kí wo̟n ó máa hùwà sí ara wo̟n gé̟gé̟ bí o̟mo̟ ìyá.
Abala kejì.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àǹfàní sí gbogbo è̟tó̟ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̟rò̟ ìyàtò̟ è̟yà kankan s̟e; ìyàtò̟ bí i ti è̟yà ènìyàn, àwò̟̟̟, ako̟-n̅-bábo, èdè, è̟sìn, ètò ìs̟èlú tàbí ìyàtò̟ nípa èrò e̟ni, orílè̟-èdè e̟ni, orírun e̟ni, ohun ìní e̟ni, ìbí e̟ni tàbí ìyàtò̟̟ mìíràn yòówù kó jé̟. Síwájú sí i, a kò gbo̟dò̟ ya e̟nìké̟ni só̟tò̟ nítorí irú ìjo̟ba orílè̟-èdè rè̟ ní àwùjo̟ àwo̟n orílè̟-èdè tàbí nítorí ètò-ìs̟èlú tàbí ètò-ìdájó̟ orílè̟-èdè rè̟; orílè̟-èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̟ ìs̟àkóso ilè̟ mìíràn, wo̟n ìbáà má dàá ìjo̟ba ara wo̟n s̟e tàbí kí wó̟n wà lábé̟ ìkáni-lápá-kò yòówù tí ìbáà fé̟ dí òmìnira wo̟n ló̟wó̟ gé̟gé̟ bí orílè̟-èdè.
Abala ke̟ta.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wà láàyè, è̟tó̟ sí òmìnira àti è̟tó̟ sí ààbò ara rè̟.
Abala ke̟rin.
A kò gbo̟dò̟ mú e̟niké̟ni ní e̟rú tàbí kí a mú un sìn; e̟rú níní àti ò wò e̟rú ni a gbo̟dò̟ fi òfin dè ní gbogbo ò̟nà.
Abala karùn-ún.
A kò gbo̟dò̟ dá e̟nì ké̟ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̟ o̟mo̟ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̟dá ènìyàn.
Abala ke̟fà.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a kà á sí gé̟gé̟ bí ènìyàn lábé̟ òfin ní ibi gbogbo.
Abala keje.
Gbogbo ènìyàn ló dó̟gba lábé̟ òfin. Wó̟n sì ní è̟tó̟ sí àà bò lábé̟ òfin láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní è̟tó̟ sí ààbò tó dó̟gba kúrò ló̟wó̟ ìyàsó̟tò̟ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti è̟tó̟ kúrò ló̟wó̟ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti s̟e irú ìyàsó̟tò̟ bé̟è̟.
Abala ke̟jo̟.
E̟nì kò̟ò̟kan lórílè̟-èdè, ló ní è̟tó̟ sí àtúns̟e tó jo̟jú ní ilé-e̟jó̟ fún ìwà tó lòdì sí è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí gé̟gé̟ bó s̟e wà lábé̟ òfin àti bí òfin-ìpìlè̟ s̟e là á sílè̟.
Abala ke̟sàn-án.
A kò gbo̟dò̟ s̟àdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mó̟lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí.
Abala ke̟wàá.
E̟nì kò̟ò̟kan tí a bá fi è̟sùn kàn ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba, tó sì kún, láti s̟àlàyé ara rè̟ ní gban̅gba, níwájú ilé-e̟jó̟ tí kò s̟ègbè, kí wo̟n lè s̟e ìpinnu lórí è̟tó̟ àti ojús̟e rè̟ nípa irú è̟sùn ò̟ràn dídá tí a fi kàn án.
Abala ko̟kànlá.
1. E̟nìké̟ni tí a fi è̟sùn kàn ni a gbo̟dò̟ gbà wí pé ó jàrè títí è̟bi rè̟ yóò fi hàn lábé̟ òfin nípasè̟ ìdájó̟ tí a s̟e ní gban|gba nínú èyí tí e̟ni tí a fi è̟sùn kàn yóò ti ní gbogbo ohun tí ó nílò láti fi s̟e àwíjàre ara rè̟. 
2. A kò gbo̟dò̟ dá è̟bi è̟s̟è̟ fún e̟nìké̟ni fún pé ó hu ìwà kan tàbí pé ó s̟e àwo̟n àfojúfò kàn nígbà tó jé̟ pé lásìkò tí èyí s̟e̟lè̟, irú ìwà bé̟è̟ tàbí irú àfojúfò bé̟è̟ kò lòdì sí òfin orílè̟-èdè e̟ni náà tàbí òfin àwo̟n orílè̟-èdè àgbáyé mìíràn. Bákan náà, ìje̟níyà tí a lè fún e̟ni tó dé̟s̟è̟ kò gbo̟dò̟ ju èyí tó wà ní ìmúlò ní àsìkò tí e̟ni náà dá è̟s̟è̟ rè̟. 
Abala kejìlá.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a má s̟àdédé s̟e àyo̟júràn sí ò̟rò̟ ìgbésí ayé rè̟, tàbí sí ò̟rò̟e̟bí rè̟ tàbí sí ò̟rò̟ ìdílé rè̟ tàbí ìwé tí a ko̟ sí i; a kò sì gbo̟dò̟ ba iyì àti orúko̟ rè̟ jé̟. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò lábé̟ òfin kúrò ló̟wó̟ irú àyo̟júràn tàbí ìbanijé̟ bé̟è̟.
Abala ke̟tàlá.
1. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti rìn káàkiri ní òmìnira kí ó sì fi ibi tó bá wù ú s̟e ìbùgbé láàrin orílè̟-èdè rè̟. 
2. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti kúrò lórílè̟-èdè yòówù kó jé̟, tó fi mó̟ orílè̟-èdè tirè̟, kí ó sì tún padà sí orílè̟-èdè tirè̟ nígbà tó bá wù ú. 
Abala ke̟rìnlá.
1. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wá ààbò àti láti je̟ àn fàní ààbò yìí ní orílè̟-èdè mìíràn nígbà tí a bá ń s̟e inúnibíni sí i. 
2. A kò lè lo è̟tó̟ yìí fún e̟ni tí a bá pè lé̟jó̟ tó dájú nítorí e̟ s̟̟è̟ tí kò je̟ mó̟ ò̟rò̟ ìs̟èlú tàbí ohun mìíràn tí ó s̟e tí kò bá ète àti ìgbékalè̟ Ajo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé mu. 
Abala ke̟è̟é̟dógún.
1. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè kan. 
2. A kò lè s̟àdédé gba è̟tó̟ jíjé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè e̟ni ló̟wó̟ e̟nìké̟ni láìnídìí tàbí kí a kò̟ fún e̟nìké̟ni láti yàn láti jé̟ o̟mo̟ orílè̟-èdè mìíràn. 
Abala ke̟rìndínlógún.
1. To̟kùnrin tobìnrin tó bá ti bàlágà ló ní è̟tó̟ láti fé̟ ara wo̟n, kí wó̟n sì dá e̟bí ti wo̟n sílè̟ láìsí ìkanilápá-kò kankan nípa è̟yà wo̟n, tàbí orílè̟-èdè wo̟n tàbí è̟sìn wo̟n. E̟tó̟ wo̟n dó̟gba nínú ìgbeyàwó ìbáà jé̟ nígbà tí wo̟n wà papò̟ tàbí lé̟yìn tí wó̟n bá ko̟ ara wo̟n. 
2. A kò gbo̟dò̟ s̟e ìgbeyàwó kan láìjé̟ pé àwo̟n tí ó fé̟ fé̟ ara wo̟n ní òmìnira àto̟kànwá tó péye láti yàn fúnra wo̟n. 
3. E̟bí jé̟ ìpìlè̟ pàtàkì àdánidá ní àwùjo̟, ó sì ní è̟tó̟ pé kí àwùjo̟ àti orílè̟-èdè ó dáàbò bò ó. 
Abala ke̟tàdínlógún.
1. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti dá ohun ìní ara rè̟ ní tàbí láti ní in papò̟ pè̟lú àwo̟n mìíràn. 
2. A kò lè s̟àdédé gba ohun ìní e̟nì kan ló̟wó̟ rè̟ láìnídìí. 
Abala kejìdínlógún.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ sí òmìnira èrò, òmìnira è̟rí-o̟kàn àti òmìnira e̟ sìn. E̟tó̟ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̟ e̟ sìn tàbí ìgbàgbó̟ e̟ni. Ó sì fún e̟yo̟ e̟nì kan tàbí àkójo̟pò̟ ènìyàn 